YBH 607

IGBALA ni, igbala ni

1. IGBALA ni, igbala ni,
Awa elese nfe;
Nitori ninu buburu,
T’ a se l’ awa nsegbe.

2. Ise owo wa ti a nse,
O nwi nigba gbogbo
Pe igbala ko si nibe,
Ise ko le gba ni.

3. Awa nsebo, awa nrubo,
A nkorin a si njo;
Sugbon a ko ri igbala,
Ninu gbogbo wonyi.

4. Nibo ni igbala gbe wa?
Fi han ni, fi han ni;
B’ o wa loke, bi isale,
B’ o ba mo wi fun wa.

5. Jesu ni se Olugbala,
Jesu l’ Oluwa wa;
Igbala wa li owo re,
Fun awa elese.

6. Wa nisisiyi, wa toro,
Ife wa ninu re;
Enyin t’ o se ‘buru l’ o pe,
E wa gba igbala.

(Visited 659 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you