1. ITAN iyanu t’ ife! So fun mi lekan si,
Itan iyanu t’ ife! Ti dun l’eti kikan!
Awon Angeli rohin re, awon oluso si gbagbo
Elese iwo ki yio gbo? Itan iyanu t’ife.
Iyanu! Iyanu!
Iyanu! Itan iyanu t’ ife!
2. Itanu iyanu t’ ife! B’ iwo tile sako,
Itan iyanu t’ ife! Sibe o npe l’oni;
Lat’ ori oke Kalfari, lati orisun Krystali;
Lati isedale aiye; Itan iyanu t’ ife.
3. Itan iyanu t’ ife! Jesu ni isimi;
Itan iyanu t’ ife! Fun awon oloto,
T’ o simi n’ ilu nla orun. Pel’awon t’ o saju wa lo;
Nwon nko orin ayo orun, itan iyanue t’ ife.
(Visited 5,237 times, 1 visits today)