1. K’ A to sun, Olugbala wa,
Fun wa n’ ibukun ale;
A jewo ese wa fun O,
Iwo l’o le gba wa la.
Bi ile tile su dudu,
Okun ko le se wa mo;
Iwo Eniti ki s’are
Nso awon enia Re.
2. B’ iparun tile yi wa ka,
Ti ofa nfo wa koja,
Awon angeli yi wa ka,
Awa o wa lailewu.
Sugbon b’ iku ba ji wa pa,
T’ ibusun wa d’ iboji,
Je k’ ile mo wa s’ odo Re
L’ ayo at’ Alafia.
3. Ni irele, a f’ ara wa
Sabe abo Re, Baba;
Jesu, ‘Wo t’o sun bi awa,
Se orun wa bi Tire.
Emi Mimo, rado bow a,
So wa l’ okunkun oru,
Tit’ awa o fi ri ojo
Imole aiyeraiye.
(Visited 4,155 times, 2 visits today)