1. OJO oni lo tan,
Oru sunmole:
Okunkun ti de na,
Ile si ti su.
2. Okunkun bo ile,
Awon ‘rawo yo;
Eranko at’ eiye,
Lo si ‘busun won.
3. Jesu f’ orun didun,
F’ eni alare;
Je ki ibukun Re,
Pa oju mi de.
4. Je k’ omo kerekere,
La ara rere;
S’ oloko t’ ewu nwu
Ni oju omi.
5. Ma to ju alaisan,
Ti ko r’ orun sun;
Da olosa lekun
L’ona ibi won.
6. Ninu gbogbo oru,
Je k’ angeli Re,
Ma se oluso mi,
Lori eni mi.
7. Gbat’ ile ba si mo,
Je k’ emi dide,
B’ omo ti ko l’ ese,
Ni iwaju Re.
8. Ogo ni fun Baba,
Ati fun Omo,
Ati f’ Emi Mimo,
Lai ati lailai.
(Visited 1,552 times, 1 visits today)