1. WO Imole! larin okun aiye,
Ma sin mi lo.
Okunkun su, mo si jina s’ ile,
Ma sin mi lo.
To ‘sise mi: bi ona ti jin to,
Nki o bere; ‘sise kan to fun mi.
2. Nigbakan ri, emi ko be O pe
Ma sin mi lo;
Beni nko fe O; sugbon nigbayi
Ma sin mi lo;
Afe aiye ni mo ti nto lehin,
Sugbon Jesu, ma ranti igba ni.
3. Ipa Re l’o ti ndi mi mu, yio si
Ma sin mi lo;
Ninu ere ati yangi aiye,
Ma sin mi lo.
Titi em’ o fi ri awon wonni
Ti mo fe, ti nwon ti f’ aiye sile.
4. Ko to d’ igba na, lona aiye yi
T’ Iwo ti rin,
Ma sin mi lo Jesu Olugbala
S’ ile Baba;
Ki nle simi lehin ija aiye
Ninu imole ti ko nipekun.
(Visited 2,467 times, 1 visits today)