YBH 64

ERO didun kan nso

1. ERO didun kan nso
S’ okan mi firifiri,
Mo sunmo ‘le mi l’ oni,
Ju bi mo ti sunmo ri.

2. Mo sunmo, ‘te nla ni
Mo sunmo’ okun kristali,
Mo sunmo, ‘le Baba,
Nibi ‘bugbe pupo wa.

3. Mo sunm’ opine mi,
T’ a so eru kale,
T’ a gb’ agbelebu sile,
T’ a sib ere gba ade.

4. Lagbedemeji eyi,
N’ isan-omi dudu:
Ti a o la koja dandan
K’ a to de imole na.

5. Jesu, jo se mi pe,
So ‘gbagbo mi di lile:
Je kin mo p’ O sunmo mi,
Li eti bebe iku.

6. Ki nmo p’ O sunmo mi,
Gba mba njin si koto:
O le je pe mo nsunmo ‘le
Sunmo ju bi mo ti ro.

(Visited 604 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you