YBH 65

BABA, a tun pade l’ oko Jesu

1. BABA, a tun pade l’ oko Jesu,
A si wa teriba lab’ ese Re;
Si O l’ a tun fe gb’ ohun wa s’ oke
Lati wa anu, lati ko ‘rin ‘yin.

2. A yin O fun itoju ‘gbagbogbo,
‘Jojumo l’ a o ma so t’ ise Re:
Wiwa l’aiye wa, anu Re ha ko?
Apa Re ki O si fi ngba ni mora?

3. O se! a ko ye fun ife nla Re,
A sako kuro lodo Re poju:
Sugbon kikankikan ni O si npe;
Nje, a de, a pada wa ‘le, Baba.

4. Nipa oko t’ o bor’ ohun gbogbo,
Nipa ife t’ o ta ‘fe gbogbo yo,
Nipa eje ti a ta fun ese,
S’ ilekun anu, si gbani s’ ile.

(Visited 807 times, 2 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you