1. IWO imole okan mi,
Li odo Re oru ko si,
Ki kuku aiye ma bo O
Kuro l’ oju iranse Re.
2. Nigbat’ orun ale didun
Ba npa ipenpeju mi de,
K’ ero mi je lati simi
Lai, l’aiya Olugbala mi.
3. Ba mi gbe l’ oro tit’ ale
Laisi Re, emi ko le wa;
Ba mi gbe gbat’ ile ba nsu.
Laisi Re, emi ko le ku.
4. B’ awon otosi omo Re
Ta ‘pa si oro Re l’ oni,
Oluwa sise ore Re,
Ma je k’ a joko si ese.
5. Bukun fun awon alaisan,
Ninu opo ibukun Re;
K’ orun alawe l’ale yi,
Dabi orun omo titun.
6. Sure fun wa nigbat’ a ji,
K’ a to m’ ohun aiye yi se.
Titi awa o de b’ ife
T’a o si de ijoba Re.
(Visited 667 times, 1 visits today)