1. OLUWA, ojo t’ O fun wa pin
Okunkun si de l’ ase Re
‘Wo l’ a korin owuro wa si,
Iyin Re y’o m’ale wa dun.
2. A dupe ti Ijo Re ko nsun,
B’ aiye ti nyi lo s’ imole,
O si nsona ni gbogbo aiye,
Ko si simi t’ osan-t’ oru.
3. B’ ile si tin mo lojojumo
Ni orile at’ ekusu,
Ohun adura ko dake ri,
Be l’ orin iyin ko dekun.
4. Orun t’ o wo fun wa, si ti la
S’ awon eda iwo-orun,
Nigbakugba lie nu si nso
Ise ‘yanu Re di mimo.
5. Be, Oluwa, lai n’ijoba Re,
Ko dabi ijoba aiye;
O duro, o sin se akoso
Tit’ eda Re o juba Re.
(Visited 1,028 times, 1 visits today)