1. L’ OJU ale, ‘gbat’ orun wo,
Nwon gbe abirun wodo Re:
Oniruru ni aisan won,
Sugbon nwon f’ayo lo le won
2. Jesu a de loj’ ale yi,
A sunmo, t’awa t’arun wa,
Bi a ko tile le ri O,
Sugbon a mo p’ O sunmo wa.
3. Olugbala, wo osi wa:
Omi ko san, ‘mi banuje,
Omi ko ni ife si O,
Ife elomi si tutu.
4. Omi mo pe, asan l’aiye
Beni nwon ko f’aiye sile;
Omi l’ore ti ko se ‘re
Beni nwon ko fi O s’ ore.
5. Ko s’ okan ninu wa t’ o pe,
Gbogbo wa si ni elese;
Awon t’ o si nsin O toto
Mo ara won ni alaipe.
6. Sugbon Jesu Olugbala,
Eni bi awa n’ Iwo se:
‘Wo ti ri ‘danwo bi awa,
‘Wo si ti mo ailera wa.
7. Agbar’ owo Re wa sile,
Oro Re si li agbara:
Gbo adura ale wa yi,
Ni anu, wo gbogbo wa san.
(Visited 1,498 times, 1 visits today)