YBH 620

BABA jowo gb’ adura wa

1. BABA jowo gb’ adura wa,
Bi a tin lo loju omi;
Iwo ma je ebute wa,
Si ma je ile isimi.

2. Jesu Olugbala ‘wo ti
O ti mu ‘ji dake roro;
Ma je ayo fun asofo,
F’isimi f’okan aibale.

3. ‘Wo Emi Mimo eniti
O tan mole nijo kini;
Je k’ ibukun at ipa Re
Tu wa ninu l’akoko yi.

4. ‘Wo Olorun Metalokan,
Ti awa nsin ti awa nbo,
Ma se ‘bi ‘sadi wa l’ aiye
Si je ibi isimi wa.

(Visited 301 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you