YBH 621

BABA wa Olodumare

1. BABA wa Olodumare,
‘Wo t’ o kawo igbi omi,
‘Wo t’ o ti f’ ipo okun fun.
Ti ko le ri ibe koja;
Gbo ti wa, gbat’ a nke pe O,
F’ awon t’ o rin l’oju omi,

2. Olugbala ‘wo t’ oro Re,
Mu igbi omi pa roro,
Iwo t’ o rin l’ori omi,
T’ O sun b’ enipe ko si nkan,
Gbo ti wa, gbat’ a nke pe O,
F’ awon t’ o rin l’oju omi,

3. ‘Wo Emi Mimo t’ o rado
B’ omi aiye nijo kini,
T’ o mu ‘binu re pa roro
Oluwa ‘mole ati ‘ye;
Gbo ti wa, gbat’ a nke pe O,
F’ awon t’ o rin l’oju omi,

4. Metalokan, Alagbara,
Wo awon t’ o wa loj’ omi,
Dabobo won lowo omi,
Ati ina ati ota’
Si je k’iyin Re ma dide
L’or’ ile ati lor’ omi.

(Visited 173 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you