YBH 622

OLORUN so wa n’nu oko

1. OLORUN so wa n’nu oko Larin omi jinjin, S’ oluso wa bati nwa lo, Ninu ajin oru. 2. Eru ko ye ki o ba wa, Larin iji ti nja, Niwon gba t’ O wa nitsi Larin omi ti nru. 3. Iparoro ati iji, T’ o nkoja lori ‘le, Iwo ni o da gbogbo won, Nwon wa nikawo Re. 4. Nigbat’ awon Aposteli, Wa lori ‘gbi okun, Ase kan lat’ odo Re wa, Mu dake roro wa. 5. Gbati iji to buru ju, Ba nru l’ atokan wa, Oluwa ma sai ba wag be F’ alafia ba wag be. 6. Ninu wahala aiye yi, Ma se amona wa, Titi ao fi de ‘le rere, Nibi t’ ese ko si.

(Visited 232 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you