YBH 623

APATA wa n’ ile are

1. APATA wa n’ ile are,
Ojiji Re bo si iyanrin,
O npe awon ero ti nkoja,
Lati wa si boji l’ aginju.

Refrain
Etise t’ e o ku? Etise t’ e o ku?
Nigbati Apata Abo wa? Etise t’ e o ku?

2. Kanga kan wa li aginju kan,
Omi re npe l’ ohun iyanu,
“Elese ti orungbe ngbe,
Wa mu lofe, iwo yio ye.”

Refrain
Etise t’ e o ku? Etise t’ e o ku?
Nigbati Apata Abo wa? Etise t’ e o ku?

3. Agbo nla wa t’ ilekun re si,
F’ agutan t’ o sonu lor’ oke
Oluso aguntan gun oke,
O nwa agutan Re t’ sonu.

Refrain
Etise t’ e o ku? Etise t’ e o ku?
Nigbati Apata Abo wa? Etise t’ e o ku?

4. Agbelebu wa ‘bi Jesu ku,
Eje Re nsan nitori ese,
O je ebo fun elese,
Lofe fun eniti o wo ‘le,
Etise t’ e o ku? Etise t’ e o ku?
‘Gbati agbelebu wa f’ elese

Refrain
Etise t’ e o ku? Etise t’ e o ku?
Nigbati Apata Abo wa? Etise t’ e o ku?

(Visited 245 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you