YBH 624

GBATI ‘ji goke l’ ona re

1. GBATI ‘ji goke l’ ona re,
T’ o f’ aniyan kun okan mi,
N’ gbekele w’ oke, wipe,
“Mo mo p’ Oluwa wa n’ tosi.”
“Ma beru” b’ oju orun su,
E gbekele Olugbala,
O ngbo, O si mbe nitosi,
O wi fun o pe “ma foya.”

Refrain
Sa wo, Jesu nwi jeje pe,
E gbekele atoko nyin,
Galili nru ‘mi l’ aiye yi,
“Emi pelu re, ma foya.”

2. Mase beru, Olugbala,
Wa n’ ibi itoko loni,
Y’o m’ oko gunle lailewu,
F’ iyemeji, eru sile
O te l’ oju iru omi,
O mu itura wa fun o,
Gbekele On y’o gba tire la,
Bi t’ ori omi Galili gbani.

Refrain
Sa wo, Jesu nwi jeje pe,
E gbekele atoko nyin,
Galili nru ‘mi l’ aiye yi,
“Emi pelu re, ma foya.”

3. Olugbala mo gbeke l’ O,
Mo be O le eru mi lo,
Mo mo p o mu m’ gunle n’ iye
B’ o ti wu ki ‘ji na le to,
Sa t’ oju orun su t’ igbi ga,
Emi ki o pe O lasan;
Ma wi fun mi pe, “emi ni.”
Sa mu irumi dake je.

Refrain
Sa wo, Jesu nwi jeje pe,
E gbekele atoko nyin,
Galili nru ‘mi l’ aiye yi,
“Emi pelu re, ma foya.”

(Visited 528 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you