1. SION yara, k’ o je ise giga re,
So f’ aiye pe Olorun ni mole,
Eni to da ‘won orilede ko fe,
K’ enikan segbe s’ inu okunkun.
Je gbogb’ eda gbo ‘yin alafia,
‘Hin rere pe Jesu ti r’ elese pada.
2. W’ egbegberun ti won sun sinu ese,
B’ a ti de won, sinu tubu ese,
Lai reni so ‘ku Olugbala fun won,
Tab’ iye t’ O fun won ninu ‘ku Re.
3. Kede f’ enia ati orile-ede,
Pe Ife ni Olorun to da won,
So p’ O re ‘ra re sile lati gb’ eda,
O ku li aiye k’ eda le gb’ orun,
4. Ran omokunrin nyin ki won j’ ise na,
N’ oro re fun won ni ‘rin ajo won,
S’ adura fun won lat’ okan ki won segun,
Jesu y’o san ohun t’o na pada fun o.
5. O npada bo, ara Sion k’ O to de,
Je gbogb’ okan mo ‘gbala ore -ofe Re,
Ma je nikan nin’ awon ti O gbala,
S alaipade Re nipa ‘jata re.
(Visited 278 times, 1 visits today)