1. ITAN kan wa f’ awon orile,
Ti yio tun okan won se,
Itan otito ti o si dun,
Itan alafia on ‘mole,
Itan alafia on ‘mole,
Refrain
Tori okunkun yio di oye,
Oye y’o o di osan gangan,
Ijoba nla Krist y’o gba aiye,
Joba ‘fe at’ imole.
2. A ni orin kan ko f’ orilede,
Ti yio gb’ okan won s’ Oluwa,
Orin t’ a fi segun Esu,
Ao se oko ao si run ‘da,
Ao se oko ao si run ‘da,
Refrain
Tori okunkun yio di oye,
Oye y’o o di osan gangan,
Ijoba nla Krist y’o gba aiye,
Joba ‘fe at’ imole.
3. A ni ise kan je f’ orile-ede,
P’ Oluwa to j’oba loke,
Ti ran ‘mo Re lati gba wa la,
O fi han w ape ‘Fe l’ Olorun,
Pe Ife ni Olorun.
Refrain
Tori okunkun yio di oye,
Oye y’o o di osan gangan,
Ijoba nla Krist y’o gba aiye,
Joba ‘fe at’ imole.
4. A l’ Olugbala kan fi han ‘raiye,
En’ to koja nu ‘banuje,
Ki gbogbo enia agbaiye,
Le gb’ otito oro Olorun,
Le gb’ otito oro Olorun,
Refrain
Tori okunkun yio di oye,
Oye y’o o di osan gangan,
Ijoba nla Krist y’o gba aiye,
Joba ‘fe at’ imole.