1. WA, obirin, e ko
Orin iye nipa
Olugbala,
Krist, ‘Mole Olorun,
Krist, t’ O jinde n’ipa,
Krist, t’ O de nyin l’ ade,
On ni k’e yin.
2. E o awon ‘mode
Ati arabinrin
N’ ile gbogbo,
Fun awon elese,
F’ awon alailera,
At’ eni okunkun
Ma gbadura.
3. Sise pelu ‘gboiya,
Ojumo fere mo
Eni ife.
‘Rawo yio tan fun nyin,
Inu nyin yio si dun,
Ati nipa ‘fe Re
E ma reti.
4. ‘Gbat ‘kore ba de
Aka Oluwa wa
Yio kun pupo.
‘Reti Onirele,
Krist, ti gbogbo wa nwa,
Krist, y’ o fun nyin l’ ere
Pelu ayo.
Support Yoruba Baptist Hymns
Every week, thousands of believers use YorubaBaptistHymns.com to access Yoruba Baptist hymns for worship and ministry.
In the last 6 months alone, people searching for Yoruba Baptist hymns found this platform over 297,000 times on Google, with more than 48,000 visitors every month.
If this platform has blessed you or your church, consider helping sustain this hymn archive so it remains available for worshippers around the world.
Support the Hymn Archive