1. T’ IFE Jesu t’o wa mi,
Gbat’ mo nu n’ ese;
T’ ore ofe t’ o mu mi
Pada bo sin’ agbo;
Ti giga jinle anu,
To jin ju okun lo,
To si ga j’ awon, orun,
L’ orun mi y’o ma je.
Refrain
Dun si b’ odun ti nkoja,
Dun si b’ odun ti nkoja,
Ife na nkun f’ayo;
Ife Jesu ndun si,
Dun si b’ odun ti nkoja.
2. On ti rin ni Judea,
L’ ona ti aiye yi;
Opo enia nyi ka,
Lati r’ or’ ofe Re;
On w’ onirobinuje,
On m’ afoju reran;
Sibe okan Re noga
N’ ife ani f’ emi.
Refrain
Dun si b’ odun ti nkoja,
Dun si b’ odun ti nkoja,
Ife na nkun f’ayo;
Ife Jesu ndun si,
Dun si b’ odun ti nkoja.
3. Ife ‘yanu l’ o mu U
Jiya lati gba wa
Ti ko f’ ibaraje ru
Irora ‘gbekele,
Pel’ awon Mimo logo,
Ka gbohun wa soke,
Tit’ aiye at’ Orun kun
Fun’ yin Olugbala.
Refrain
Dun si b’ odun ti nkoja,
Dun si b’ odun ti nkoja,
Ife na nkun f’ayo;
Ife Jesu ndun si,
Dun si b’ odun ti nkoja.