1. ENIKAN se ise wura;
On wa b’ ore nigba aini;
Enikan ko orin ayo,
Nmu sanma dan ni gbogb’ ojo.
Refrain
Eni na ni o bi?
Eni na ni o bi?
2. Enikan ns’ ole ngba gbogbo,
O nte ‘tanna aiye mole
Enikan f’ aiye re sofo,
O ti lo emi re lasan.
Refrain
Eni na ni o bi?
Eni na ni o bi?
3. Enikan ri adun l’ aiye
Ni fifi ini re tore;
Enikan ja ij’ akoni
Ni fif’ emi lele f’ oto.
Refrain
Eni na ni o bi?
Eni na ni o bi?
4. Enikan f’ imole k’ ojo,
On f’ aisimi le oru lo;
Nise ayo alafia,
Daju aiye re ko le pin.
Refrain
Eni na ni o bi?
Eni na ni o bi?
(Visited 514 times, 1 visits today)