1. ORE ni Jesu fun mi, tito ‘b’ Ife Re po,
Ife nla ti ko le sa,
Bi mo tile s’ aito,
S’ife Re yi ni mo ti se;
Sugbon ngba mo kunle,
Mo jewo gbogb’ aise mi,
Eru ese sib o.
Refrain
Beni Jesu ri, O nle okunkun lo,
Beni Jesu ri, lojojo npa mi mo,
Beni Jesu ri, l’ aginju yi ja,
Gege bi ife nla Re.
2. Nigbat’ okunkun ‘yonu sub o sanma l’ oke
Ti nko le ri Olugbala,
Mo gbagbe ife nla Re;
Lat ite Anu Re l’ orun,
O r’ ainireti mi,
L’anu O m’ awosanma si,
O fi han pe On wa.
Refrain
Beni Jesu ri, O nle okunkun lo,
Beni Jesu ri, lojojo npa mi mo,
Beni Jesu ri, l’ aginju yi ja,
Gege bi ife nla Re.
3. A! mo le Korin titi, orin ife Jesu,
Orin anu itoju Re,
L’or’ elese b’ emi,
Ife nla Re ‘li aiye, igbi lile gboran,
Jesu pase pe “dake je,”
O le okunkun lo.
Refrain
Beni Jesu ri, O nle okunkun lo,
Beni Jesu ri, lojojo npa mi mo,
Beni Jesu ri, l’ aginju yi ja,
Gege bi ife nla Re.