1. IMOLE k’ okan mi loni,
T’ o logo t’ o si ndan,
T’ o tan ju t’ awosanma lo,
Jesu n’ imole mi.
Refrain
A, imole, ‘mole Mimo,
B’ akoko ti nfayo sare lo
Ti Jesu nfoju ‘fe Re han
Imole kun okan mi.
2. Orin kun okan mi loni,
Orin si Oba na,
Bi Jesu ti nteti sile,
Gbo’ orin ti nko le mo.
Refrain
A, imole, ‘mole Mimo,
B’ akoko ti nfayo sare lo
Ti Jesu nfoju ‘fe Re han
Imole kun okan mi.
Stanza 3 of Hymn 640
Ayo kun okan mi loni,
Oluwa ko jinna,
Alafia mbe l’ okan mi,
Or’ofe farahan.
Refrain
A, imole, ‘mole Mimo,
B’ akoko ti nfayo sare lo
Ti Jesu nfoju ‘fe Re han
Imole kun okan mi.
4. Ireti k’ okan mi loni,
Orin ‘yin at’ ife,
Ibukun ti On fi fun mi,
Ayo t’ o wa loke.
Refrain
A, imole, ‘mole Mimo,
B’ akoko ti nfayo sare lo
Ti Jesu nfoju ‘fe Re han
Imole kun okan mi.