1. JESU nfe k’ a f’ imole ti o pe tan,
Bi fitila kekere ninu oru;
L’ aiye okunkun yi, ka si tan,
N’ ipo t’ iwo wa, at’ emi pelu.
2. Jesu nfe k’ a ko tan ‘mole fun U,
On mo daju b’ imole wa nsokunkun;
Lati orun l’ On wo, k’a ma tan,
N’ ipo t’ iwo wa, at’ emi pelu.
3. Jesu nfe k’ a tan, nigbana f’ awon,
T’ o wa n’ okunkun ‘banuje aiye yi,
F’ otosi elese k’a ma tan,
N’ ipo t’ iwo wa, at’ emi pelu.
4. Jesu nfe k’ a tan, ‘nu ise fun U,
Ka m’ awon t’ o sina n’ese pada wa;
On o ran wa lowo k’ a ma tan,
N’ ipo t’ iwo wa, at’ emi pelu.
(Visited 493 times, 1 visits today)