1. JESU ni gbogb’ aiye fun mi,
Iye at’ ayo mi,
Agbara mi lojojumo,
L’ aisi Re mo subu;
Ni ‘banuje On ni mo to,
Nitori ko s’ eni bi Re,
Ni ‘banuje O m’ ayo wa,
Ore mi.
2. Jesu ni gbogb’ aiye fun mi,
Ore n’ igba ‘danwo,
Fun ibukun On ni mo to,
Mo ni lopolopo.
O m’ orun ran, at’ ojo ro,
Ikore wura si npo si,
Imole, imole, etc
Orun ojo at’ ikore.
Ore mi.
3. Jesu ni gbogb’ aiye fun mi,
Nko si ni tan On je,
O ti buru to bi mo se;
Gbat’ On ko tan mi je?
Nitito Re nko le sina,
On toju mi losan loru,
Ni tito Re losan loru,
Ore mi.
4. Jesu ni gbogb’ aiye fun mi,
Nko fe elomiran,
Ngo gbekele nisisiyi,
T’ ojo aiye nkoja;
Aiye ewa lodo re na,
Aiye ewa ti ko l’ opin,
Iye, ayo ainipekun,
Ore mi.
(Visited 2,093 times, 1 visits today)