1. NGO korin itan ‘yanu na,
Ti Jesu t’ o ku fun mi,
B’ On ti fi ‘le ogo sile,
F’agbelebu Kalfari.
Refrain
A ngo korin tan ‘yanu na –
Ti Jesu t’ o ku fun mi
Pelu awon ninu ogo,
Yi okun iyun na ka.
2. Mo ti nu , Jesu si ri mi,
Agutan t’ o ti sako;
N’ apa ife Re yi mi ka,
Fa mi pada s’ ona Re.
Refrain
A ngo korin tan ‘yanu na –
Ti Jesu t’ o ku fun mi
Pelu awon ninu ogo,
Yi okun iyun na ka.
3. Mo f’ ara pa Jesu wo mi,
Isubu so mi d’ oku,
Kuro n’ iberu ‘nu foju,
O ti so mi d’ omnira.
Refrain
A ngo korin tan ‘yanu na –
Ti Jesu t’ o ku fun mi
Pelu awon ninu ogo,
Yi okun iyun na ka.
4. On y’o so mi titi omi,
Odo na nkan mi l’ese;
Y’o gbe mi koja l’ailewu;
Ngo r’ awon olufe mi.
Refrain
A ngo korin tan ‘yanu na –
Ti Jesu t’ o ku fun mi
Pelu awon ninu ogo,
Yi okun iyun na ka.