YBH 658

NIGBA igbi aiye ba dide si o

1. NIGBA igbi aiye ba dide si o,
T’ okan re baje pe gbogbo nkan segbe,
Siro ibukun re, ka won lokokan,
Enu y’o ya o fun nkan t’ Oluwa t’se.

Refrain
Ro ‘bukun re ka won lokokan,
Ro ohun t’ Olorun se fun o;
Ro ‘bukun re, ka won lokokan,
Ro ‘bukun re, ri nkan t’ Olorun ti se.

2. Eru aniyan ha tin pa okan re?
Agbalebu ti ‘wo nru ha si wuwo?
Siro ibukun re le ‘yemeji lo,
Iwo y’o si korin b’ ojo ti nkoja.

Refrain
Ro ‘bukun re ka won lokokan,
Ro ohun t’ Olorun se fun o;
Ro ‘bukun re, ka won lokokan,
Ro ‘bukun re, ri nkan t’ Olorun ti se.

3. Nigbat’ ini elomi kun o loju,
Ranti Krist n ‘oro aimoye fun o,
Siro ibukun re t’ owo ko le ra,
At’ ere re lorun, ile re l’ oke.

Refrain
Ro ‘bukun re ka won lokokan,
Ro ohun t’ Olorun se fun o;
Ro ‘bukun re, ka won lokokan,
Ro ‘bukun re, ri nkan t’ Olorun ti se.

4. Beni larin ija b’ o ti wu ko ri,
Mase ba okan je mo p’ Olorun mbe,
Siro ibukun re, Angeli y’o wa,
Fun ranwo on ‘tunu d’opin ajo re.

Refrain
Ro ‘bukun re ka won lokokan,
Ro ohun t’ Olorun se fun o;
Ro ‘bukun re, ka won lokokan,
Ro ‘bukun re, ri nkan t’ Olorun ti se.

(Visited 2,068 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you