1. ENYIN ero, nibo l’e nlo
T’ enyin t’ opa lowo nyin?”
A nrin ajo mimo kan lo,
Nipa ase Oba wa,
Lori oke on petele,
A nlo s’ afin Oba rere,
A nlo s’ afin Oba rere,
A nlo s’ ile t’ o dara,
A nlo s’ afin Oba rere,
A nlo s’ ile t’ o dara.
2. Enyin ero, e so fun ni,
T’ ireti ti enyin ni?
Aso mimo, ade ogo
Ni Jesu y’o fi fun wa;
Omi iye l’ a o ma mu;
A o si b’ Olorun wa gbe,
A o si b’ Olorun wa gbe,
N’ ile mimo didara
A o si b’ Olorun wa gbe,
N’ ile mimo didara.
3. E ko beru ona t’ e nrin,
Enyin ero kekere?
Ore airi npelu wa lo,
Awon Angeli yi wa ka,
Jesu Kristi l’ amona wa;
Y’o ma so wa, y’o ma to wa,
Y’o ma so wa, y’o ma to wa,
Ninu ona ajo wa;
Y’o ma so wa, y’o ma to wa,
Ninu ona ajo wa.
4. Ero, a le ban yin kegbe,
L’ ona ajo s’ ile na?
Wa ma kalo, wa ma kalo,
Wa si egbe ero wa,
Wa, e ma se fi wa sile,
Jesu nduro, O nreti wa,
Jesu nduro, O nreti wa,
N’ ile mimo t’ o dara;
Jesu nduro, O nreti wa,
N’ ile mimo t’ o dara.