YBH 7

DIDUN n’ ise na, Oba mi

1. DIDUN n’ ise na, Oba mi,
Lati ma yin oruko Re,
Lati se ‘fe Re l’ owuro,
Lati so-oro Re l’ale.

2. Didun l’ojo ‘simi mimo
Lala ko si fun mi loni:
Okan mi, ma ko ‘rin iyin
Bi harpu Dafidi didun.

3. Okan mi o yo n ‘n’ Oluwa,
Y’o yin ise at’ oro Re
Ise ore Re tip o to!
Ijinle si ni imo re.

4. Emi o yan ipo ola
‘Gb’ ore-ofe ba we mi nu;
Ti ayo pupo si ba mi,
Ayo mimo lat ‘ oke wa.

5. ‘Gbana, ngo ri, ngo gbo, ngo mo
Ohun gbogbo ti mo ti nfe;
Gbogbo ipa mi y opapo
Lati se ‘fe Re titi lai.

(Visited 902 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you