YBH 8

EWOLE f’ Oba, ologo julo

1. EWOLE f’ Oba, ologo julo,
E korin ipa ati ife Re;
Alabo wa ni, at’ Eni Igbani,
O ngbe ‘nu ogo, eleru ni iyin.

2. E so t’ ipa Re, e so t’ ore Re:
‘Mole l’ aso Re gobi Re orun,
B’ ara ti nsan ni ‘keke, ibinu Re;
Ipa ona Re ni a ko si le mo.

3. Aiye yi pelu ekun re gbogbo,
Olorun, agbara Re l’ o da won:
O fi idi re mu ‘le, ko si le yi,
O si f’ okun se oja igbaiya re.

4. Itoju Re wa lara gbogbo won,
Ninu afefe, ninu imole;
Itoju Re wa nin ‘ odo ti o nsan,
O si wa ninu iri ati ojo.

5. Awa erupe, aw’ alailera,
‘Wo l’ a gbekele, O ki o da ni;
Anu Re ronu, o si le de opin
Eleda, Alabo, Olugbala wa.

6. ‘Wo alagbara, onife julo,
B’ awon angeli ti yin O loke,
Be l’ awa eda Re niwon t’ a le se
A o ma juba Re, a o ma yin O.

(Visited 10,090 times, 10 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you