1 YIN Oluwa, oro didun
Yin oru ‘dake je,
Gbogbo aiye so ogo Re,
Yin, irawo ‘mole.
2. Yin, enyin iji t’ o dide
N’ igboran s’ ase Re
K’ oke at’ igi eleso
Dapo yin Oluwa.
3. E fi ete nyin mimo yin
Enyin ogun orun;
Ogo, ola at’ agbara
Fun Oba ‘yeraiye.
4. Eyin, enyin mimo ti nyo
Nihin. Nin ‘ase Re
Orun adura eniti
Nt’ ori pepe g’ oke
5. E yin gbogbo ise Re ti
O wa n’ ikawo Re,
Oluwa, ola Re ti to!
Okan mi yin l’ ogo.
(Visited 774 times, 1 visits today)