YBH 70

ORUN si nyara wo

1. ORUN si nyara wo,
Ojo nku lo;
K’ ife ko ji dide,
K’ o rubo asale.

2. B’ ori Jesu ti te
L’ agbelebu,
T’ O jowo emi Re
Le baba Re lowo.

3. Be ni mo f’ emi mi
Fun: l’ a fun tan,
N’ ipamo Re mimo
L’ emi gbogbo saw a.

4. Nje emi o simi
Lodo Re je;
Laiye k’ ero kanso
Yo okan mi l’ enu.

5. ‘Fe Tire ni sise
L’ onakona:
Ku n’nu onikare,
N’nu On, l’ ona gbogbo.

6. Bel’ emi ye: sugbon
Emi ko, On
Ni mbe laye n’nu mi,
L’ agbara ife Re.

7. Metalokansoso
Olorun kan,
Lai ki nsa je Tire,
K’ On je t’ emi titi.

(Visited 266 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you