YBH 71

OGO f’ Olorun l’ ale yi

1. OGO f’ Olorun l’ ale yi
Fun gbogbo ore imole,
So mi, Oba awon oba
Labe ojiji iye Re.

2. Oluwa, f’ ese mi ji mi,
Nitori Omo Re loni;
K’ emi le wa l’ Alafia
Pelu Iwo ati aiye.

3. Ko mi ki nwa, kin le ma wo
Iboji t’emi b’ eni mi;
Ko mi, ki nku, kin le dide
Ninu ogo l’ ojo ‘dajo.

4. Je k’ okan mi le sun le O
K’ orun didun p’ oju mi de;
Orun ti y’o m’ ara mi le
Ki nle sin O li owuro.

5. Bi mo ba dubule laisun,
F’ ero orun kun okan mi
Ma je ki nl’ ala buburu
Ma je k’ ipa okun bo mi.

6. Yin Oluwa, gbogbo eda
Ti mbe n’ isale aiye yi;
E yin l’ oke, eda orun,
Yin Baba, Omo on Emi.

(Visited 938 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you