1. JESU, bukun wa k’ a to lo:
Gbin oro Re si aiya wa:
K’ o si mu k’ ife gbigbona
Kun okan ilowo wa:
Refrain
Nigba iye at’ iku wa,
Jesu, jare se ‘mole wa.
2. Ile ti su orun ti wo;
‘Wo si ti siro iwa wa:
Die nj’ isegun wa loni
Isubu wa l’ o papoju:
Refrain
Nigba iye at’ iku wa,
Jesu, jare se ‘mole wa.
3. Jesu,dariji wa: fun
L’ ayo, ati eru mimo,
At’ okan ti ko l’ abawon
K ‘a bale jo O l’ajotan:
Refrain
Nigba iye at’ iku wa,
Jesu, jare se ‘mole wa.
4. Lala dun, ‘tor’ Iwo se ri:
Aniyan fere, O se ri:
Ma je k’ a gbo t’ ara nikan
K’ a ma bo sinu idewo.
Refrain
Nigba iye at’ iku wa,
Jesu, jare se ‘mole wa.
5. A mbe O f’awon alaini,
F’ elese at’ awon t’ a fe:
Je ki anu Re mu wa yo,
‘Wo Jesu, l’ ohun gbogbo wa
Refrain
Nigba iye at’ iku wa,
Jesu, jare se ‘mole wa.
6. Jesu, bukun wa, – ile su:
Tikalare wa ba wag be:
Angel’ rere nso ile wa;
A tun f’ ojo kan sunmo O.
Refrain
Nigba iye at’ iku wa,
Jesu, jare se ‘mole wa.
Support Yoruba Baptist Hymns
Every week, thousands of believers use YorubaBaptistHymns.com to access Yoruba Baptist hymns for worship and ministry.
In the last 6 months alone, people searching for Yoruba Baptist hymns found this platform over 297,000 times on Google, with more than 48,000 visitors every month.
If this platform has blessed you or your church, consider helping sustain this hymn archive so it remains available for worshippers around the world.