1. OLUGBALA, a tun fe f’ ohun kan,
Yin oruko Re k’ a to tuka lo;
N’ ipari sin, a dide lati yin:
A ‘o si kunle fun ibukun Re.
2. F’ Alafia fun wa, b’ a tin re ‘le
Je k’ a pari ojo yi pelu Re;
Pa aiya wa mo, si so ete wa.
T’ afi pe oruko Re n’ ile yi.
3. F’ alafia fun wa l’ oru oni,
So okunkun re d’ imole fun:
Ninu ewu yo awon omo Re.
Okun on ‘mole j’ okanna fun O.
4. F’ Alafia fun wa ni aiye wa,
Re wa l’ ekun, k’ O si gbe wa n’ ija:
‘Gbat’ O ba si f’ opin s’ idamu wa,
Pe wa, Baba, s’ orun Alafia.
(Visited 523 times, 1 visits today)