1. OLORUN wa aiyeraiye,
Ore Re ntan loke orun:
Oto Re y’o la kuku ja
Ti o bo ife Re loju.
2. Ore Re duro titi lai,
Bi oke ti f’ idi mule;
Ogbon ni ise owo Re,
Idajo Re jinle pupo.
3. Ore-ofe Re tip o to,
Nibit’ itunu wa ti nwa!
Awon ‘mo Adam’ n’nu ponju,
Nsa sabe oji iye Re.
4. Ni inu ese ile Re,
Sibe ao ri onje didun;
Nibe l’ anu nsan bi odo,
O mu igbala wa fun wa.
(Visited 259 times, 1 visits today)