YBH 78

MO korin ipa Olorun

1. MO korin ipa Olorun,
T’ O gbe oke dide,
T’ O tan odo tin san kiri,
T’ O si k’ orun giga.

2. Mo korin ogbon t’ o mu ki
Orun ko ran l’ osan
Osupa nran nip’ ase Re,
Irawo gb’ oro Re.

3. Mo korin ore Oluwa,
T’ O f’ onje kun aiye;
O fi oro Re da eda,
O si pe nwon dara.

4. Ko s’ eweko tab’ itanna,
Ti ko f’ ogo Re han;
Oj’ orun nsu, iji si nja,
Nip’ ase lat’ oke.

5. Eda t’ o gba ‘ye lodo Re,
Wa labe ‘toju Re;
Ko s’ ibi kan t’ a le sa lo,
Ti Olorun ko si.

(Visited 403 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you