1. EJE k’ a f’ inu didun,
Yin Oluwa Olore;
Anu Re, o wa titi,
L’ ododo dajudaju.
2. On, nipa agbara Re,
F’ imole s’ aiye titun;
Anu Re, o wa titi,
L’ ododo dajudaju.
3. O mbo awon alaini,
Ati gbogbo alaye;
Anu Re, o wa titi,
L’ ododo dajudaju.
4. O bukun ayanfe Re
Li aginju iparu;
Anu Re, o wa titi,
L’ ododo dajudaju.
5. E je k’ a f’ inu didun,
Yin Oluwa Olore;
Anu Re, o wa titi,
L’ ododo dajudaju.
(Visited 11,980 times, 9 visits today)