1. YIN Olorun Oba wa,
E ko orin ogo si,
‘Tor’ anu Re wa sibe,
L’ ododo dajudaju.
2. Yin, n’tori t’ O da orun
Lati ran l’ ojojumo,
Ati osupa l’ oru,
Ti o ntan ‘mole ‘jeje.
3. Yin, n’torr t’ O m’ ojo ro,
Lati mu irugbin ru,
O si pase fun ile,
K’ o mu opo eso wa.
4. Yin fun ikore oko,
O mu ki aka wa kun;
Yin f’ onje t’ o ju yilo,
Eri ‘bukun ailopin.
5. Ogo f’ Oba Olore,
Ki gbogbo eda korin,
Ogo fun Baba, Omo,
At’ Emi, Metalokan.
(Visited 619 times, 1 visits today)