1. IFE l’ Olorun: anu Re
Mole s’ ona wa gbogbo;
O ns’ ayo ji, O ndin ‘se ku:
Ogbon nla ni olorun.
2. Iku at’ ayida nsise;
Enia nbaje, aiye nlo,
Sugbon anu Re ki ye lai;
Anu nla ni Olorun.
3. Akoko t’o dab’ o su ju,
Y’o fi ore nla Re han;
‘Mole Re ti ‘n’ okun se wa;
Ogbon nla ni Olorun.
4. O fi lala inu aiye
So ‘reti on ‘tunu po;
Ogo Re ntan nibi gbogbo:
Anu nla ni Olorun.
(Visited 285 times, 1 visits today)