YBH 84

ONA ara l’ Olorun wa

1. ONA ara l’ Olorun wa
Ngba sise Re l’ aiye;
A nri ‘pase Re lor’ okun,
O ngun igbi l’ esin.

2. Ona Re enikan ko mo,
Awamaridi ni;
O pa ise ijinle mo,
O sin se bi Oba.

3. Ma beru mo, enyin mimo,
Orun t’ o su be ni,
O kun fun anu: y’o rojo
Ibukun sori nyin.

4. Mase da Oluwa l’ ejo,
Sugbon gbeke re le;
‘Gbat o ro pe O binu,
Inu Re dun si .

5. Ise Re fere ye wan a,
Y’o ma tan siwaju;
Bi o tile koro loni,
O mbo wa dun lola.

6. Afoju ni alaigbagbo,
Ko mo ‘se Olorun;
Olorun ni Olutumo,
Y’o m’ ona Re ye ni.

(Visited 5,894 times, 5 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you