1. OLUWA l’ O nso mi:
Y’o te fe mi lorun:
Niwon bi a ti je okan,
Kil’ emi ‘ba tun fe?
2. O sin mi lo sibi
Ti papa orun nhu,
Sibit’ omi ‘ye nsan jeje,
At’ ekun igbala.
3. Bi mo ba sina lo,
A m’ okan mi pada,
A to mi s’ ona Re pipe,
‘Tori oruko Re.
4. Bi mba nri ‘ranwo Re,
Eru ko le ba mi;
Bi mo tile nla ‘ku koja,
Oluso mi nsun mi.
5. Loj’ awon ota mi,
O te onje fun mi;
O f’ ibukun kun ago mi,
Ayo gb’ ori miga.
6. Opo ife Re y’o
Kun ojo ni t’o ku;
Emi k’yo si f’ ile Re ‘le,
K’yo ye so t’ iyin Re.
(Visited 396 times, 1 visits today)