1. SAJU wan so, Olorun,
Fere ogun ti ro;
Ninu papa isegun,
N’ago Re l’ao ma gbe
Anu re fun wa l’okun
N’ipalemo f’ ogun na
A si wa nkorin ‘segun,
S’oba aiyeraiye.
2. Saju wan so, Olorun
D’opin ogun ese;
T’iwa mimo yio si maa
Korin Alafia;
Tori kii ‘se ‘ro ida
Tab’ ariwo ilu
Bikose ‘fe at’ anu
Nio mu ‘job’ orun de.
3. Saju wan so, Olorun
Laiberu l’awa nlo,
Nibikibi t’O ba wa,
Ayo l’o wa n’be
A gb’ agbelebu Re soke;
O sin se mole wa lo;
Ade duro d’asegun
Saju nso, Olorun.
(Visited 438 times, 1 visits today)