1. MA wo ‘le, Jesu t’ a nreti,
T’a bi lati gba ni la!
Gba wa low’ ese at’ eru,
K’ a r’ isimi ninu Re.
2. Ipa at’ itunu Israel;
Ireti awon mimo;
Olufe gbogbo orile,
Ayo okan ti nreti.
3. A bi O lati gb’ eda la,
Enia – sugbon Olorun –
Lati job alai ninu wa,
Mu ‘joba rere Re wa.
4. Nipa Emi Re t’ o wa lai,
Nikan joba ninu wa;
Nipa ‘toye Re t’ o po to,
Gbe wa s’ ite ogo Re.
(Visited 422 times, 1 visits today)