YBH 90

GBO ‘gbe ayo! Oluwa de

1. GBO ‘gbe ayo! Oluwa de,
Jesu t’ a seleri;
Ki gbogbo okan mura de,
K’ ohun mura ko ‘ rin

2. O de lati t’ onde sile,
L’ oko eru Esu;
‘Lekun ‘de fo niwaju Re,
Sekeseke ‘rin da

3. O delarin ‘baje aiye
Lati tan ‘mole Re,
Lati fun awon afoju
N’ iriran f’ oju won.

4. O de! ‘Tinu f’ okan ‘rora,
Iwosan f’ agbogbe;
O de pel’ opo ‘sura Re
Fun awon talaka.

5. Hosanna wa, Oba ‘lafia
Ao kede bibo Re;
Gbogbo orun y’o ma korin
Oruko t’ a feran.

(Visited 428 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you