1. ILU t’ o dara po l’ aiye;
Betlehem’, ‘wo ta won yo;
Ninu re l’ Oluwa ti wa
Lati j’ oba Israel’.
2. Ogo ti irawo ni ju
Ti orun owuro lo;
Irawo t’ o kede Jesu
Ti a bi ninu ara.
3. Awon ‘logbon ila-orun
Mu ‘ yebiye ore wa:
E wo, bi nwon ti fi wura,
Turari, ojia fun.
4. Jesu, ‘Wo ti keferi nsin
Li ojo ifihan Re;
Fun O, Baba l’ a f’ ogo fun
Ati fun Emi Mimo.
(Visited 293 times, 1 visits today)