Yoruba Baptist Hymns
IKU l’ opin ohun gbogbo
First time here? Explore the hymn tools.
Selected words
Verse 1
IKU l’ opin ohun gbogbo;
B’ o ti wu k’ emi gun,
Egun ni ko le sai ma se
T’ a ti fi eda gun.
Verse 2
Lehin ojo die l’ aiye,
T’ a lo ninu lala,
Ninu aisan at’ ailera,
Iko iku yio de.
Verse 3
Erin l’ oro, ekun l’ ale,
Ayo on ‘banuje,
Ojo ebi, ojo ayo
L’ opin ninu iku.
Verse 4
A! egun ‘re f’ awon t’ o ku
Ninu Olugbala;
Nwon ku si iponju gbogbo,
Nwon ji sinu ogo.
Verse 5
Ona l’ o je sinu iye
F’ awon onigbagbo,
Tani few a nihin titi
Ninu aisimi yi?
Verse 6
Gba wa lowo iku keji,
Jesu Olugbala,
K’ a r’ iye ninu iku Re,
Lehin lala aiye.
From Yoruba Baptist Hymnshttps://yorubabaptisthymns.com/hymn/iku-l-opin-ohun-gbogbo/
Conversation 0 comments
Share a reflection or ask a question. Comments are reviewed before they appear.
Report a lyric correction
Include the verse and a hymnbook or source reference. Submissions are reviewed before any lyrics change.
Share anonymously
No account is required. Anonymous comments include the city and country you choose to share.