NIWAJU ite anu Re
First time here? Explore the hymn tools.
Verse 1
NIWAJU ite anu Re,
Jesu, a tun ko ‘ra wa de,
A wa toro idariji,
Fun majemu t’ a ti baje.
Verse 2
A wa se otun ileri,
Ipa Re l’ o o le di wa mu,
Lati ma to awon ‘mo wa
Si inu isin pipe Re.
Verse 3
Ran wa lowo lati ma wa
‘Gbala awon ojulumo;
K’ a le ma hu iwa eto,
K’ a rin dede l’ oju aiye.
Verse 4
Jek’ a le se b’ ileri wa,
Lati ma je olotito;
K’ a fi ara wa s’ apere
Ninu iwa at’ ise wa.
Verse 5
K’ a takete si aheso,
At’ isoro eni lehin;
K’ a mase binu rekoja,
K’ oya w a lati mu ‘ja tan.
Verse 6
K’ a si ma toju ara wa
Ninu ife arakunrin;
Ki a ma se iranlowo
Ninu aisan at’ iponju.
Verse 7
Ninu ise rere gbogbo,
Mu w ape, Olugbala wa;
Si jek’ a le se ife Re
B’ awon mimo tin se l’ orun.
Conversation 0 comments
Share a reflection or ask a question. Comments are reviewed before they appear.
Report a lyric correction
Include the verse and a hymnbook or source reference. Submissions are reviewed before any lyrics change.
Share anonymously
No account is required. Anonymous comments include the city and country you choose to share.